Nkan oṣù àkọ́kọ́ rẹ ń bọ̀ — kò sì nílò kí o múra bí ẹni tó ń lọ ogun. O kàn nílò àlàyé tó tọ́. 🩸📋
Ìbàlágà máa ń mú àyípadà púpọ̀ wá, fún ẹnikẹ́ni tó ní ilé ọmọ, ọ̀kan lára àwọn tó tóbi jùlọ ni ríri nkan oṣù. Ó sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ láàárín ọjọ́ orí 8 sí 13, ṣùgbọ́n ara ẹnìkọ̀ọ̀kan ní àkókò tirẹ̀.
Fídíò yìí ṣàlàyé bí circle nkan oṣù ṣe ń ṣiṣẹ́ gan-an — láti ìgbà tí ẹyin bá jáde títí di ìgbà tí àwọ̀ inú ilé ọmọ bá ṣubú. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmì PMS bíi ìrora inú, ìyípadà ìṣesí, wíwú, àti àárẹ̀, àti ohun tí o lè ṣe nípa wọn.
Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé — àwọn ènìyàn kan ní ìrora, àwọn mìíràn kò ní. Àwọn kan ní ẹ̀jẹ̀ púpọ̀, àwọn mìíràn kò ní. Kò sí “ọ̀nà kan ṣoṣo” láti nírìírí nkan oṣù. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ ohun àdánidá.
Ríri nkan oṣù rẹ kìí ṣe ìparí ayé. Àmì ni pé ara rẹ ń dàgbà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ. 💛
Ẹ tẹ̀lé The Smile Outreach fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé. A dúpẹ́ lọ́wọ́ alájọṣe wa AMAZE fún àtìlẹ́yìn wọn. FB/IG: @amazeparents.africa YouTube: @AmazeAfrica


