Ní ìṣẹ́jú kan, o ń rẹ́rìn-ín. Ní ìṣẹ́jú tó tẹ̀lé e, o fẹ́ sunkún. Ṣé ó mọ ọ́? O kò ń pàdánù ara rẹ — o ń dàgbà ni. 💛🧠
Nígbà ìbàlágà, ara rẹ máa ń mú àwọn kẹ́míkà tuntun jáde tí a ń pè ní hormones. Àwọn hormones wọ̀nyí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere, ṣùgbọ́n wọ́n tún lè mú kí ìmọ̀lára rẹ máa yípo. Ayọ̀ ní àkókò kan, ìbínú tàbí ìbànújẹ́ ní àkókò mìíràn — láìsí ìdí kankan. Ìyẹn sì jẹ́ ohun àdánidá pátápátá.
Ṣùgbọ́n èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé — tí o bá ti ń ní ìbànújẹ́ tó ga, àárẹ̀, àìnírètí, tàbí àníyàn fún ju ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì lọ, ìyẹn lè jẹ́ àmì pé o ní depression. Depression kìí sì ṣe ohun ìtìjú. Ó lè kan ẹnikẹ́ni, níbikíbi, ẹni tó wù kí ó jẹ́.
Tí ìyẹn bá jẹ́ ìwọ, jọ̀wọ́ bá ẹnìkan sọ̀rọ̀ — òbí, olùkọ́, olùdámọ̀ràn, tàbí àgbàlagbà èyíkéyìí tí o gbẹ́kẹ̀lé. O kò ṣí nìkan. Rárá. 💛
Ẹ tẹ̀lé The Smile Outreach fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé. A dúpẹ́ lọ́wọ́ alájọṣe wa AMAZE fún àtìlẹ́yìn wọn. FB/IG: @amazeparents.africa YouTube: @AmazeAfrica
